Wednesday, February 22, 2012

Part 3 - Black History Month = Yoruba History Month!

Ta lo mo mi - Kini oruko mi?

*This yoruba heroes story comes curtesy of Engineer Simons Latunde - Addey, thank you very much sir! It is an excerpt on black history month from the website www.abeokuta.org and is written in Yoruba and modified for our quiz by this blog editor. God bless you if you can read and understand it completely. Good luck solving this one...


Oṣù fún ìtàn adúláwọ̀ ní Amẹ́ríkà - february 2012

Oṣù kéjì ọdún ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (USA) jẹ́ àsìkò ti wọn máa ṣe ìrántí ìtàn àwọn adúláwọ̀ ti o jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nínú oṣù yìí, ní àwọn ará ilẹ̀ Amẹ́ríkà máa bojúwo ẹ̀hìn láti rántí onírúurú ohun ti o ṣẹlẹ̀ si ènìyàn aláwọ̀-dúdú ni ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni sáà kan. Iṣe ribiribi ti Martin Lurther King àti àwọn aṣíwájú òmìrán, ṣe láti jà fún ẹ̀tọ́ (àti ìgbélarugẹ ipò) àwọn adúláwọ̀ ni ilẹ̀ Amẹ́ríkà pẹ̀lú ọ̀nà látí pèsè idọ́gbandọ́gba nípa:

- ẹ̀tọ́ fún adúláwọ̀ lati dìbò,

- àyípadà àwọn òfin ti o ya ọmọ aláwọ̀-dúdú sọ́tọ̀ ni ilé-ìwé,

- iyawó láti ra ile,

- àti àwọn ètò ìrànlọ́wọ́ míràn,

O jẹ́ nkan ìwuri nlá fún gbogbo ènìyàn aláwọ̀-dúdú káàkiri àgbáyé.

Nítọrí àṣeyọrí ìjà fún ẹ̀tọ́ àwọn adúláwọ̀ ní ilẹ̀ Amerika, ní àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá fi pọ̀ ka kiri àwọn ìpínlẹ̀ àti ìlú Amerika. Ko si ìlú pàtàkì ní Amerika, ti ẹ ti ní ri ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá, bo jẹ ìlú Atlanta (ní ìpínlẹ̀ Georgia) tàbí ìlú Houston (ní ìpínlẹ̀ Texas) tàbí ìlú nlá New York.

Gégébí ẹ ti mọ̀, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn baba-nlá àwọn adúláwọ̀ ti o jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní wọn kó lẹrú láti ilẹ̀ Yorùbá ní ayé àtijọ́.

Kini oruko mi?

Emi je Ọ̀kan nínú wọn ní. Mo si jẹ́ ọmọ bíbí Ẹgba, ti wọn bí ní ọdún 1738. Wọn kó mi l’eru láti ilẹ̀ Yorùbá ni ọdún 1760. Mo jẹ́ ọ̀kan lará àwọn jagunjagun ti o jà nínú Ogun Òmìnira fún orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní ọdún 1775 – 1783. 

L'ehin ogun, won ni won o fun wa ni ile (land) ti ara wa sugbon ni igba ti won o fun wa ni ile yen bi won ti wi, awa omo adulawo ko ra wa jo lati lo da ibi ti a o gbe sile ni ibi ti a npe ni Nova Scotia.

Igbati o se di e, mo se irin ajo lo si ilu oke (England) lati lo bere fun eto fun awon adulawo ti won ko l'eru tele. A bere pe ki won je ki a pada si ile Africa ni ilu ti a npe ni Freetown l'eni, ni Sierra Leone. Won gba fun wa. Won si fun wa ni oko oju omi (ship) ti yio gbe wa de 'be ati awon ohun ti a o lo n'ibe. Awa bi egberun meta si gbe'ra dide l'ati lo da ile Freetown s'ile. Ko pe ti a pada de Freetown ti iba (malaria) fi ba mi, ki n' to se alaisi.












Ta ni mo je? Ki l'oruko mi?


Ire o!

Funke Abolade, M.D.

Akowe Faaji.






6 comments:

  1. MR THOMAS PETERS

    ReplyDelete
  2. My guess is Marcus Garvey.

    ReplyDelete
  3. Mr Thomas Peters

    Rakiya Adediji.

    ReplyDelete
  4. Wow! Very good guesses so far...I would never have guessed either of these 2 names but then what do I really know of yoruba history....

    Keep 'em coming, the guesses...picking first correct entry tomorrow as there is another submitted quiz coming up ...

    ReplyDelete
  5. Congratulations again, Mrs Adagunodo. O ga o! Mr Thomas Peters it is! Your prize awaits you at the next meeting in Hoover, Alabama. More quizzes and prizes to come this february..

    ReplyDelete

Go on - Leave a message!